Wednesday, August 28, 2019


IPESE FUN OHUNKOHUN

Eran maalu ekiri kan ao so fun awon eleran kiwon bawa ge rubutu ko tobi die ao wa fi iyereosun tefa osameji soju opon ifa aofi ekiri eran yi siwaju odu yen aofi obi alawe merin kan si eti opon ifa naa ao wa pe ohunre sinu odu yen Lenin naa aofi eran ko ifa naa aofi sinu awo ipese tuntun kan ao bu epo lelori aofi obi yen bere ibiti won yio ti gba ipese na ni adugbo wa Toba di aro ojo keji aolo mu awo ipese yi wale lati tun fi se ipese yi nigba miran

OFORE:Ake kaaka wolu3× Abirin kakaka wolu3× A gbe ori iroko ke kakaka3× Ibiti edarisi ni edari si3× ibiti e pin jeki si lepin jeki3× Eyin ni igba Erin ri tiwon nfi eyin lu eyin omo opere opere3× Eyin ni igba efon ri tiwon nfiiwo lu Iwo omo ogbangandanran ogbangandanran3×Eyin naa ni igba olopere ri tiwon fi nfo janpe janpe kalu3×Ewa ni kinni igba Erin ri tiwon fi nfi eyin lu eyin omo opere opere Eni kinni igba efon ri tiwon fi nfiwo luwo omo ogbangandanran ogbangandanran Ewa ni kinni igba olopere ri tiwon fi nfo janpe janpe kalu Ero!ero!! Ero!!! Seese lodifa fun koowe ajedo eniyan mabi Aje oronro masinto Eewo ni aje ko gbodo pa omo koowe je ki aje mapa emi lol ooo Kiwon lo Lana rere gbogbo owo nlanla fun mi lati oni lo nio Nitoripe agbadikaka3× loruko tanpe ifa orunmila ninu gbogbo eye to nfo radiradi loju orun eyin iyami osoronga ati okanlerugba irunmole loba olodumare pinhun lode orun Won ni ki olodumare fowo mu ode orun ko yonda ile aye fun awon ni kiakia olodumare fowo mu ode orun osi yonda ile aye fun yin Nigbati e dele aye tan eyin iyami osoronga tunwa ba orunmila pinhun wipe ki orunmila fowo mu aaro ati osan Awon ni awon ni oru won niti orunmila bati pese fun awon loru awon yoo mase gbogbo nkan toba fe fun laro ati losan orunmila wa biwon lere wipe kinni ohun ipese naa won niki orunmila mafi eran abeje malu ekiri kan pelu iyereosun pese fun awon toba ti pe oruko awon awon yo mase gbogbo ohun tobafe fun Ipese ti eniki orunmila se lojo kinni anaa ni emi L omo L se fun yin loni yio Ti o base wipe lododo ati lotito leba nbe lode isalu aye yi ki ewa lo pese gbogbo ohun ti mo bere funmi ni kiakia bayi oo adura ohun ti abafe kiwon se fun wa ao gbe losi ibiti won tife gba.....

No comments:

Post a Comment

ASIRI BIBO OWO FUN DECEMBER

Ewe iyalode funfun 14 fun okurin 12 fun obirin ao to mefa si isale ape ao si oju re soke, ao fi eyin adiye agric meta si, ao fi meje bo lori...